Share to: share facebook share twitter share wa share telegram print page

Pascal Atuma

Pascal Atuma jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùdarí erẹ́, àti oníṣòwò.[1] Òun ni olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ TABIC Record Label, èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ agbórinjáde.

Pascal Atuma
Ọjọ́ìbíAbia State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Port Harcourt
Iṣẹ́Actor, screenwriter, film producer

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

Wọ́n bí Pascal sí ìlú Ikwuano, ní Umuahia, ìpínlẹ̀ Abia, ó sì lọ sí Government College, Umuahia, àti University of Port Harcourt, Rivers State. Ó tún lọ sí KD Conservatory-College of Film & Dramatic Arts ní Dallas, Texas, US, láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ tíátà. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ Entrepreneurship Specialization láti University of Pennsylvania.

Iṣẹ́ rẹ̀

Ó ṣàfihàn nínú àwọn fíìmù bí i Sweet Revenge, Eat my Shorts láti ọwó Lions Gate, Bloodlines, LAPD African Cops, The Other Side of Love, My American Nurse, àti Secret Past. Ó fìgbà kan jẹ́ olóòtú ètò orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán kan, èyí tí ń ṣe One-World with Pascal Atuma, àti The House of Commons. Ó jẹ́ olùdarí fíìmù Professor Johnbull fún apá mẹ́tàlá àkọ́kọ́ àti Clash (2019).

Ó ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Kastina State Ministry of Youths and Sports Development.[2]

Ayé rẹ̀

Òṣèrékùnrin náà ń gbé ní Canada.[3]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí Òṣèrẹ́

Ọdún Àkọ́lé Ipa
2004 Life in New York Oscar
2004 In His Kiss African Prince
2004 Accidental Life The Boyfriend
2005 Only in America Mandela
2006 My American Nurse Shehu
2008 Through the Glass (with Stephanie Okereke) Lawyer Robert
2009 Hurricane in the Rose Garden Dr. Joseph Shehu
2010 My American Nurse 2 Shehu
2011 Secret Past Desmond
2011 Okoto the Messenger Okoto
2012 The Mechanic-Who Is the Man Kumasi
2013 Hawa (Short) Jonas
2014 Blood Lines Icon
2016 LAPD African Cops Officer Ghana
2018 Busted Life Clerk
2018 Sweet Revenge (Short) Mr. Mandela
2019 Only You & Me (post-production) Phil
2020 Clash Chief Okereke

Gẹ́gẹ́ bí Aṣagbátẹrù fíìmù

Ọdún Àkọ́lé Ipa
2005 Only in America Producer
2006 My American Nurse Executive Producer / Producer
2009 Hurricane in the Rose Garden (Video) Producer
2010 My American Nurse 2
2011 Okoto the Messenger
2012 The Mechanic-Who Is the Man Executive Producer / Producer
2014 Blood Lines Producer
2016 LAPD African Cops Executive Producer / Producer
2018 Sweet Revenge (Short) Producer
2020 Clash

Gẹ́gé bí Òǹkọ̀tàn

Ọdún Àkọ́lé
2005 Only in America
2006 My American Nurse
2009 Hurricane in the Rose Garden (Video)
2010 My American Nurse 2 (Screenplay & Story)
2011 Okoto the Messenger
2012 The Mechanic-Who Is the Man
2014 Blood Lines
2016 LAPD African Cops
2018 Sweet Revenge (Short)
2020 Clash

Gẹ́gẹ́ bí Olùdarí

Ọdún Àkọ́lé
2006 My American Nurse
2010 My American Nurse 2
2011 Okoto the Messenger
2012 The Mechanic-Who Is the Man
2014 Blood Lines
2016 LAPD African Cops
2017 Gone To America
2018 Sweet Revenge (Short)
2020 Clash

Gẹ́gẹ́ bí ayan-òṣèré

Ọdún Àkọ́lé Ipa
2011 Okoto the Messenger Casting

Iṣẹ́ ara-ẹni

Ọdún Àkọ́lé Ipa
2018 Mister Tachyon (TV Series documentary) Dr. Tachyon

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

Atuma gba àmì-ẹ̀yẹ fún Òṣèrékùnrin tó dára jù lọ ní ọdún 2012 àti 2015, ní Golden Icons Academy Movie Awards (GIAMA). Wọ́n fún ní àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 2013, ní Los-Angeles Nollywood Film Award (LANFA) nítorí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe àti fún ipa rẹ̀ nínú iṣẹ́-tíátà. Bẹ́ẹ̀ sì ní fíìmù rẹ̀, L.A.P.D. African Cops gba àmì-ẹ̀yẹ fuhn fíìmù tó dára jù lọ ní ọdún 2015.

Àwọn ìtọ́kasí

  1. "Bad Choice Of Leaders Keeping Nigeria From Reaching Full Potential – Pascal Atuma". Independent Newspaper Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-02-22. Retrieved 2022-07-17. 
  2. Njoku, Benjamin (October 26, 2024). "Why I'm partnering with Kastina State Govt. To develop football academy.". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2024/10/why-im-partnering-kastina-state-govt-to-develop-football-academy-in-the-state/. 
  3. Onodjae, Efe (September 14, 2024). "Filmmaker, Pascal Atuma ro release movie on JAPA syndrome featuring Omoni Oboli, others". Vanguard. https://www.vanguardngr.com/2024/09/filmmaker-pascal-atuma-to-release-movie-on-japa-syndrome-featuring-omoni-oboli-others/. 
Prefix: a b c d e f g h i j k l m n o p q r s t u v w x y z 0 1 2 3 4 5 6 7 8 9

Portal di Ensiklopedia Dunia

Kembali kehalaman sebelumnya