Network of CSOs Against Trafficking, Abuse and Labour (NACTAL)
Network of CSOs Against Trafficking, Abuse and Labour jẹ́ àjọ tó ní àfojúsùn àti dáàbò bo ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn àti láti mú àwọn olùfaragbá tí wọ́n ti gbé lọ sí ìlú mìíràn lọ́nà àìtọ́, tí ó sì ti jìyà látàri ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára,[1] ìfipábánilòpọ̀ àti ìṣílọ lọ́nà àìtọ́ lòrìṣiríṣi padà bọ̀ sípò. Èróńgbà àjọ yìí ni láti ri pé àwọn olùfaragbá yìí padà bọ̀ sípò.[2] Nípa èyí, wọ́n ń mú ètò bá iṣẹ́ ọmọnìyàn àti ìdàgbàsókè dé bá ìlú.[3][4] ÌtànỌdú 2003 ni wọ́n dá àjọ NACTAL sílẹ̀, ó sì ní ajọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba àti ìgbììmọ̀ gbogboogbo ti orílẹ̀-èdè àgbáyé bíi National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons, Nigeria Police Force, Nigeria Immigration Service (NIS), European Union, International Organization for Migration, àti Nigeria Police. Àwọn àfojúsùn àti iṣẹ́ wọnÀjọ náà ń ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ bíi; gbígba àwọn olùfaragbá ìṣílọ lọ́nà àìtọ́ là,[5] ṣíṣe ìpolongo láti tako ìwà ṣíṣí àwọn èèyàn kúrò láti ibi kan sí ibòmìíràn,[6] kíkọ́ àwọn èèyàn, àti ṣíṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ètò lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan nípa lílo áwọn òté márùn-ún kan tíí ṣe; àìfààyègbà, ìdáábòbò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìfìyàjẹ àti ìgbófin kalẹ̀.[7] Awọn olùṣèjọbaÀwọn ìgbìmọ̀ alábòójútó, ìgbìmọ̀ aláṣẹ káríayé, àti àwọn agbátẹrù mẹ́fà ni ó jẹ́ olùdarí NACTAL . Bolaji Owasanoye, ni alága ìgbìmọ̀ alábòójútó, Ustaz Amin sì jẹ́ olórí ìgbìmọ̀ aláṣẹ káríayé,[8] Abdulganiyu Abubakar sì ni ààrẹ gbogboogbo.[9] Àwọn ọmọ ẹgbẹ́NACTAL ní iye omọ-ẹgbẹ́ tó ń lọ bíi àádójọ tí kìí ṣe àjọ ti ìjọba, tó ń ṣiṣẹ́ títako ìwà ṣíṣí àwọn èèyàn kúrò láti ibi kan sí ibòmìíràn lọ́nà àìtọ́ àti dídààbobo àwọn ọmọdé. Àjọ yìí sí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn tó ń rí sí dídààbobo bo àwọn olùfaragbá ìṣílọ lọ́nà àìtọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àjọ yìí ni àwọn àjọ mìíràn tó tó bíi mẹ́rìndínlógójì káàkiri orílẹ̀-èdè yìí. Awon Itokasi
|