Formula One tàbí Formula 1 tàbí F1 jẹ́ ọkọ̀ ìṣeré tó tóbi jù, èyí tí àwọn Fédération Internationale de l'Automobile (FIA) ṣe. FIA Formula One World Championship jẹ́ eré-ìdárayá ọlọ́kọ̀ àkọ́kọ́, èyí tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1950. Ọ̀rọ̀ náà formula nínú orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí àwọn òfin tí àwọn akópa eré-ìdárayá náà gbọdọò tẹ̀lé. Apá kan ìdíje Formula One máa ń ní oríṣiríṣi awakọ̀ káàkiri, èyí tí wọ́n máa ń pè ní Grands Prix. Grands Prix máa ń wáyé ní oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè ní ojú títì tí wọ́n tì pa tàbí gbàgede ìṣeré.
Ó ní ìlànà tí àwọn Grands Prix ń lò láti fi mọ olùdíje méjì tó gbégbá orókè, àkọ́kọ́ á jẹ́ awakọ, tí ẹ̀kejì á sì jẹ́ ọ̀wọ́ tó ṣe ọkọ̀ náà. Dandan ni kí awakọ kọ̀ọ̀kan ní ìwé-ẹ̀rí àṣẹ láti wa irú ọkọ̀ yìí fún ìdíje, èyí tó jẹ́ ìwé-àṣẹ tó ga jù lọ fún àwọn olùkópa ìdíje ọkọ̀ wíwà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n gbọdọ̀ lọ Grade One tracks fún ojú ọnà.
Formula One jẹ yọ láti World Manufacturers' Championship (1925–1930) àti European Drivers' Championship (1931–1939). Formula yìí jẹ́ àtòjọ ìlànà tí ó dé àwọn olùdíje, tí ó sì dà bí òfin tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé láti lè kópa nínú ìdíje náà. Formula One jẹ́ èyí tí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yàn ní ọdún 1946, èyí tí wọ́n bẹ̀rè sí ní fi ìdí rẹ̀ múlè láti ọdún 1947. Grand Prix àkọ́kọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin tuntun náà ni Turin Grand Prix ti ọdún 1946, èyí tí wọ́n ń lò kí Formula one tó wáyé.[2][3][4]
Ìdíje àkọ́kọ́ ni 1950 British Grand Prix, èyí tó wáyé ní Silverstone Circuit, ní United Kingdom, ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Karùn-ún ọdún 1950.[5] Giuseppe Farina, tó jẹ́ olùdíje fún Alfa Romeo ló gbégbá orókè nínú ìdíje náà, lẹ́yìn tí ó tayọ akẹgbẹ́ rẹ̀, ìyẹn Juan Manuel Fangio. Fangio ló gbégba orókè ní 1951, 1954, 1955, 1956, àti 1957.[6] Èyí sì jẹ́ àkọsílè àkọ́kọ́ fún olùdíje tó tayọ̀ jù, tí ẹnikẹ́ni ò sí ní irú àmì-ẹ̀yẹ bẹ́ẹ̀ fún ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta, àfi ìgbà tí Michael Schumacher tayọ àkọsílẹ̀ yìí. ní ọdún 2003.[6]
|url-status=