Edo State Taskforce Against Human Trafficking (ETAHT)
Edo State Task Force Against Human Trafficking (ETAHT) jẹ́ àjọ-agbófinró orílẹ̀ èdè Nigeria tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Edó gbé kalẹ̀ láti dènà kíkó ọmọ ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú àwọn orúkọ burúkú tí ó pèlé e ní ìpínlè náà. Ní báyìí, àwọn Ìpínlẹ̀ mìíràn bí i; Oǹdó, Ọ̀yọ́, Èkó, Enugu, Ekiti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wo àwòkọ́ṣe Ìpínlẹ̀ Edo láti dá àjọ agbófinró lórí ìwà ìbàjẹ́ kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ sílẹ̀.[1]. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yinka Omirogbe, ọ̀gá-àgbà àwọn adájọ́ àti Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìdájọ́ ní Ìpínlẹ̀ Edo ni Alága àjọ-agbófinró náà.[2] Lọ́dún 2017, Gómìnà Godwin Obaseki ṣe ìfilọ́lẹ̀ àjọ-agbófinró tó ń tako kiko ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ ní ìpínlè náà.[3] Wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà nílé ìṣèjọba Ìpínlẹ̀ Ẹdó ní Ìlú Benin, tí ó jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà.[4] Àjọ Edo Task Force Against Human Trafficking ni a gbọ́ pé ó ti gba àwọn arìnrìn-àjò lọ́nà àìtọ́ tó tó 5,619 padà láti orílẹ̀ èdè Libya, tí wọ́n ń gbìyànjú láti ròkè òkun sí ilẹ̀ Europe láti ọdún 2017 títí asiko yìí .[5] Wọ́n dá àjọ-agbofinro yìí sílẹ̀ pẹ̀lú aṣojú láti àjọ agbófinró lorisirisi, àwọn àjọ tí kìí ṣe tí ìjọba NGOs, àjọ NAPTIP MDAS, àjọ àwọn ẹ̀sìn gbogbo.[6] Àwọn ÀfojúsùnLáti fòpin sí òwò-ẹrú ìgbàlódé tí wọ́n ń pè ní Kíkó àwọn ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́, àti rí i pé wọ́n ran àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà padà láti gbé ìgbé ayé tó dára láwùjọ.[7] Àwọn èròǹgbà
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́
Àwọn Alábáṣepọ̀ àti Alájọṣe
Àwọn Ìtọ́kasí
|